Home
Yoruba: Awọn Èdè tí a ń lò fun Iṣẹ́-olùṣéwadìí

Ní ìpàdé àpérò tí Die Junge Akademie (German Young Academy), àwọn àjọ Olùṣèwádìí àwọn onímọ̀ (amọ̀jọ̀gbọ́n) méjìlélógún ní orílẹ̀-èdè méjìdínlógún péjọ láti ṣàpérò àti jíròrò lóríi bí èdè ṣe ń nípa lorí iṣẹ-ìwádìí àti bí ó ṣe ń ṣe ìtànká àbájáde iṣẹ́-ìwádìí náà káàkiri.
Bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kejì dé ọjọ́ kẹrin osu kẹsàn-án, Àwọn àjọ Olùṣèwádìí (amọ̀jọ̀gbọ́n) ní orílẹ̀-èdè méjìdínlógún káàkiri àwọn kọ́ńtínẹ́ǹtì (ìpín-ilẹ̀-ayé) mẹ́fà kórajọ pọ̀ ní Yunifásitì Goethe ní Frankfurt láti jíròrò lórí ipa tí èdè ń kó ní àwùjọ-ẹ̀kọ́. Ọ̀pọ̀ ìjíròrò yìí gbára lé èdè Gẹ̀ẹ́sì gẹ́gẹ́ bí èdè àmúlò nínú ìjíròrò náà. Àwọn akópa mú àwọn ìmọ̀ tí wọ́n ní nípa ẹ̀dá-èdè wọn wá fún àfiwé èrò àti pàsípààrọ̀. Wọ́n jẹ́ àwọn tí ó sẹ̀sẹ̀ ń dìde bọ̀ (ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́) ní agbo àwùjọ-ẹ̀kọ́ ní Belgium (Dutch), Colombia (Spanish), Finland (Finnish), Germany (German), Hungary (Hungarian), Indian (Assamese, Punjabi), Indonesia (Indonesian), Kenya (Kimeru), Lithuania (Lithuanian), Nepal (Nepali), Nigeria (Yorùbá), Norway (Norwegian), Palesstine (Arabic), Sudan (Arabic) and Switzerland (French, German), àti pẹ̀lú àwọn (ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́) ní agbo àwùjọ-ẹ̀kọ́ lágbàáyé (Polish, Romanian).
Iṣẹ́ ajẹmọ-ìwádìí (akadá) pẹ̀lú èdè ní ojojúmọ́, síbẹ̀ àwọn àǹfààní láti lè ronú jinlẹ̀ nípa bí èdè ṣe nípa tàbí ṣe ìrànwọ́ nípa ìkópa, ìní-àǹfààní àti ìgbéwọ̀n pẹ̀lú bí iṣẹ́-ìwádìí wọn ṣe lè dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn sọ̀wọ́n gan-an.
Àwọn ẹgbẹ́ Die Junge Akademie tí iṣẹ́ wọn jẹ mọ́ èdè ni wọ́n bẹ̀rẹ̀, tí àfojúsùn ìpàdé wọn dá lórí èdè gẹ́gẹ́ bí ògbúnná gbòǹgbò (èròjà pàtàkì) ní onírúurú èrò ní àwùjọ-ẹ̀kọ́, èyí tí ó sì lè di ohun tí ó ń fa ìyàsọ́tọ̀. Ìjíròrò wáyé lórí ipa tí èdè ń kó nínú ìbánisọ̀rọ̀ọ sáyẹ́ǹsì (ìmọ̀-ìjìnlẹ̀), àṣeyọrí akọ́ṣẹ́-mọṣẹ́ àti ohunkóhun tó níí ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ àti àyíká rẹ̀, ìpín agbára láàrin àwùjọ-ẹ̀kọ́, àwọn ànfààní (ire) tí orílẹ̀-èdè àti ríjíónì ń ní pẹ̀lú ipa ìyípadà ńlá lórí ìgbékalẹ̀ èdè.
Iṣẹ́ amọ̀jọ̀gbọ́n ń gbára lé èdè Gẹ̀ẹ́sì síwájú síi, tí ó sí ń mú àǹfààní tí ó jọjú wá, ṣùgbọ́n ó tún ń fa àwọn ìpèníjà tó lápẹrẹ. Èdè tí gbogbo àgbáyé ń lò gẹ́gẹ́ bí èdè ìbánisọ̀rọ̀ àpapọ̀ ń mú kí ìbáṣepọ̀, pàsípààrọ̀ èrò àti ìmọ̀ pẹlù, kí wọ́n sì fọwọ́sowọ́pọ̀ nínú èrò, iṣẹ́ tí ó lé mú ìdàgbàsókè wá. Síbẹ̀ ìgbara lé ìlò èdè kan soso le ṣe ìdíwọ́ fún ìkópa, kí ó sì tún mú gbèdéke bá iṣẹ́-ìwádìí, fún àwọn tí ọ̀nà wọ́n kò gba iṣẹ́ amọ̀jọ̀gbọ́n àti àwọn àwùjọ tí kì í sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Láti wò ó fún òye kíkún, àgbáyé àti agbègbè-àyíka-ẹni, iṣẹ́ ìwádìí lè jẹ́ tí àgbáyé, síbẹ̀ kò wá ní àrọ́wọ́tó àti agbègbè àwọn ara itòsí, àwọn amọ̀jọ̀gbọ́n, àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga àti àwọn tí ó ń ṣe àgbékalẹ̀ ìlànà àti òfin ní láti mọ̀ pé èdè tí a bá yàn láti fi ṣe ìwádìí jẹ́ pàtàkì nínú iṣẹ-ìwádìí yòówù-ó-jẹ́. Ìpàdé náà wá sí òpin pẹ̀lú ìfarajìn àti ìfaramọ́ lápapọ̀ láti gbé ìjíròrò yìí lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ àwọn olùkópa, ibi-iṣẹ́ wọn, àwọn ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ àti àwùjọ ẹ̀kọ́-amọ̀jọ̀gbọ́n tí ó gbòòro.